House Fellowship FEBRUARY 17, 2019
BIBELI KIKA: Ps.1:1-6
Koko Oro ninu Bibeli kika yi ni Rinrin, Di Duro ati Ji Joko nibi ti ko to si omo Olorun. Nitori a fe lati dagba ninu Emi lodun yi lati lee je Olotito si Kristi, a nilo lati mo awon to ye ka ma ba rin, awon to ye ka ma duro soro ti ati ibi ti o ye ka ma joko soro. Fun idi eyi, a o gbadura:
- Emi Mimo si mi loju kin le mo awon to ye ki n ma ba rin po ki n ma baa sina
- Emi Mimo e si mi loju inu kin le rina ri iwa awon ore ti mo ni lowolowo
- Kristi ma je ki nrin oku ona, Fi ese mi le ona iye re ti yoo silekun ibukun fun mi lojoojumo.
- Ma je ki awon asinilona aye si mi lona tabi gba mi lona iye re
- Ibi ti ko ye ki nti duro ma je ki nduro nibe
- Mo ko lati duro lona awon elese,
- Ma je ki njoko ni ibujoko awon elegan, gba agbara egan kuro laye mi.
- Ranmi lowo kin le ma se asaro ninu oro re lojoojumo, kin le rina ri awon ibukun loju ona naa
- Se mi ni igi ti a gbin seti ipa odo, ti ewe re kii re.
- Se mi ni igi eleso rere ati igi ibukun fun elomiran
- Je ki ohun gbogbo ti mo ba dawole ma se deede, ma je ki nsaseti lona mi gbogbo
- Mo agbara igbega fun ogo Kristi lodun yi
- Mo koja lo sibi giga rere aye mi lodun yi
- Mo ko lati pada leyin Kristi lodun yi
- Emi Mimo e se mi ni olooto fun ogo re lodun yi
- Gba mi lowo gbogbo arekereke Satani ki o si mu mi segun nigba gbogbo loruko Jesu
- Se mi ni orisun ibunkun agbayanu fun gbogbo eniyan to ba yi mi ka loruko Jesu oluwa.
- Jesu Omo Olorun e gba mi lowo gbogbo agbara aisan, ajalu, Iku, Ijona, ati inira loruko Jesu Kristi
- Mo wo inu majemu ominira, Iye, alaafia, igbega, aluyo, iserere, itesiwaju ati oriire lodun yi loruko Jesu Kristi.
- Jesu Kristi, se mi ni asoju re nibi gbogbo ti mo ba wa gegebi iriju rere olooto fun ogo re nikan loruko Jesu Kristi.
E fi iyin kase adura yin nile, ki enikookan jo niwaju Olorun fun idahun awon adura naa.